Konyin, ape-itewe n wo oja agbaye
Awon omo Oodua tun n gbe Yoruba ati Naijiria s'oke
Lati owo Jare Ajayi
Laipe, ape-itewe (keyboard) eyokan-soso yoo le
te iwe edekede to wu ki eniyan fe te ni agbaye. Iyan ede ti o ba je pe alifabeeti ikowe re da lori
leta ti o je jade lati inu ede Latin. Ede Yoruba ati awon
ede miran to wa ni ile Naijiria lo je pe iru alifabeeti ti
a wi yii ni won n lo.
Ohun to je nnkan iwuri nipa oro yii ni pe awon
omo Oodua ni won wa ni idi bi ape pataki yii se wa si aye ati bi yoo se di ohun ti mutumuwa n lo kaakiri agbaye.
Olobo to so Afonrere Yoruba fi han pe awon ede to je gbajugbaja gege bi ede Oyinbo
(Geesi), Faranse, Jamani, Potugi, Giriiki, Latin, Sipaniisi, Rosia ati bee bee lo ni ape yii yoo see lo fun.
Ile-ise onimo ero ode oni kan ti oruko re n je Lagos Analysis Corporation (Lancor) ni o se agbejade ape yii. Ilu Boston
ni orile-ede Amerika ni olu ile-ise yii wa. O tun ni eka pataki ni ilu Eko ni orile ede
Naijiria.
Ogbeni Adejumobi Oyegbola ati Ogbeni Walter O.
Oluwole ni won je oludari ile ise ti a wi yii. Enikeeta won ti o je alabojuto
ni Ogbeni George C.K. Van-Lare.
Ilu Eko ni won ti bi Ade Oyegbola nigba ti Walter
je omo ilu Sagamu ni ipinle Ogun.
A o se iranti pe Afonrere Yoruba ti gbe oro jade nipa awon eniyan yii tele nigba ti a n soro nipa ape itewe won eyi ti won pe ni
Konyin.
Pelu ape yii, eniyan le ko iwe ninu ede gbogbo to wa ni Naijiria – bi o ba ti je pe alifabeeti ede Latin
ni ede naa fi n kowe.
alifabeeti ikowe ti o da lorii A B D ati bee bee
lo gege bi Yoruba, Igbo, Geesi, Faranse ni apere alifabeeti to da lori ede Latin ti a n so.
Orisi ona ikowe miran to wa ni agbaye ni ti Arabiiki,
Sainiisi (Chinese), Japaniisi (Japanese to je pe o fi ara pe Sainiisi) ati bee bee lo. Omiran ni Heeburu Hebrew.
Lowo bayii, igbese ti n lo lowo lati ri pe ape
titun yi bo si ori igba ni awon ilu nla-nla kaakiri agbaye.
A o mu ekunrere alaye nipa ile ise Lancor ati
paapaa julo awon to se agbekale nnkan pataki yii wa fun yin laipe. E ku oju lona. Ire o.
OPA n mura fun ayeye odun kewaa
Egbe kan
ti idagbasoke agbegbe Oke ogun je logun, Oke Ogun Progressive (USA) Incorporated
n gbaradi fun ayeye odun kewaa ti o ti di dida sile.
Ojo kokandinlogbon osu kokanla (osu Belu) odun
yii ni ayeye naa yoo waye.
Agbegbe Queens ni ilu New York ni ayeye naa yoo si ti sengere.
Awon omo-bibi agbegbe Oke ogun ni ipinle Oyo ni
o da egbe yii sile. Gege bi alukoro egbe naa, Ogbeni Sunday Adegbola se fi to wa leti, ona ati ri pe, “ a ko ara wa
jo, a si jo n se asepo, a si tun n jiroro lori idagbasoke enikookan wa ati ti ilu ti a ti wa” ni o se okunfa dida egbe
yii sile.
Lenu igba ti egbe yii di kikojo, opo nnkan idagbasoke
lo ti gbe se. Pataki ninu eyi ni iranlowo owo goboi ti won n fun awon akekoo to wa ni ile-eko giga ni Naijiria. Egberun meedogbon
naira ni won n fun akekoo kookan lodoodun. Akekoo bii metala ni n je anfaani yii lodun kan.
Titi ti akekoo bee yoo si fi pari eko re ni ile eko giga ni yoo ma je anfaani naa niwon igba ti o ba ti n se daadaa ninu eko
re. Odun bii merin sehin ni eto pataki yii ti bere.
Oloye Gbode
ri gbo pe egbe naa yoo maa se iranlowo fun awon omo egbe to ba jade ile iwe ni Amerika paapaa bere lati odun yii lo.
Lara awon to se agbateru egbe yii ni Alagba Tolani
Ogundiran ti o je Aare egbe naa ki o to di oloogbe ni odun 2004, Ojogbon Segun Odesina, Alhaji Yekini Salami, Oloye R. Adedokun
Atitebi, Diakoni Timothy Ayinla, Ogbeni Toye Okesola, Alhaja Yinka Atitebi, Oloye Yinka Ayedun, Ogbeni Sunday Adegbola, Alhaja
Adunola Salami, Ogbeni Adejare ati Alagba Olaleye.
Lara awon ti won
fun dijo n gbe egbe yii ro ni Iyaafin Ayinla, Ogbeni Omodewu, Ogbeni Adesola Ige, Ogbeni Akande, Iyaafin Oladokun ati Iyaafin
Akande ati awon jankan jankan miran.