Konyin, ape-itewe wo oja agbaye
Omo Oodua tun n gbe ilu abinibi won laruge
Lati owo Jare Ajayi
Opon-itewe (keyboard) ti n te iwe ni ede yowu ki eniyan fe te ni agbaye ti wa ni oja bayii. Iyan ede ti o ba je pe alifabeeti ikowe re da lori
leta ti o je jade lati inu ede Latin. Ede Yoruba ati awon
ede miran to wa ni ile Naijiria ati ni Afrika lo je pe iru
alifabeeti ti a wi yii ni won n lo.
Ohun to je nnkan iwuri nipa oro yii ni pe awon omo Oodua ni won wa ni idi
bi ape pataki yii se wa si aye ati bi yoo se di ohun ti mutumuwa n lo kaakiri agbaye.
Olobo to so Oloye Gbode fi han pe awon ede to je gbajugbaja gege bi ede Oyinbo
(Geesi), Faranse, Jamani, Potugi, Giriiki, Latin, Sipaniisi, Rosia ati bee bee lo ni opon itewe yii yoo see lo fun.
Ile-ise onimo ero ode oni kan
ti oruko re n je Lagos Analysis Corporation (Lancor) ni o se agbejade ape yii. Ilu Boston ni orile-ede Amerika ni olu ile-ise
yii wa. O tun ni eka pataki ni ilu Eko ni orile ede Naijiria.
Ogbeni Adejumobi Oyegbola ati Ogbeni Walter O. Oluwole ni won je oludari ile ise ti a wi yii. Enikeeta won ti o je alabojuto ni Ogbeni George C.K. Van-Lare.
Eko ni George yii wa lati maa se konkari ise Lancor. Oun ati Iyaafin Funmilayo ni won jo n se eyi lohun-un.
Ilu Eko ni won ti bi Ade Oyegbola nigba ti Walter je omo ilu Sagamu ni ipinle
Ogun.
Pelu ape yii, eniyan le ko iwe ninu ede gbogbo
to wa ni agbaye – bi o ba ti je pe alifabeeti ede Latin ni ede naa fi n kowe.
Alifabeeti ikowe ti o da
lorii A B D ati bee bee lo gege bi Yoruba, Igbo, Geesi, Faranse ni apere alifabeeti
to da lori ede Latin ti a n so.
Orisi ona ikowe miran to wa ni agbaye ni ti Arabiiki, Sainiisi (Chinese),
Japaniisi (Japanese to je pe o fi ara pe Sainiisi) ati bee bee lo. Omiran ni Heeburu Hebrew.
Pelu aseyori yii, awon omo Oodua ti n je ki o seese fun wa lati ri pe awa
naa n fi ese won ese pelu awon eniyan miran nibikibi lagbanla aye.
Oluwa yoo tubo maa se alekun imo olukaluku wa, ase.
OPA n mura fun ayeye odun kewaa
Egbe kan ti idagbasoke agbegbe Oke ogun je logun, Oke Ogun Progressive (USA) Incorporated n gbaradi fun ayeye odun kewaa ti o ti di dida sile.
Ojo kokandinlogbon
osu kokanla (osu Belu, November) odun yii ni ayeye naa yoo waye.
Agbegbe
Queens ni ilu New York ni ayeye naa yoo si ti sengere.
Awon omo-bibi
agbegbe Oke ogun ni ipinle Oyo ni o da egbe yii sile. Gege bi alukoro egbe naa, Ogbeni Sunday Adegbola se fi to wa leti, ona
ati ri pe, “ a ko ara wa jo, a si jo n se asepo, a si tun n jiroro lori idagbasoke enikookan wa ati ti ilu ti a ti wa”
ni o se okunfa dida egbe yii sile.
Lenu igba
ti egbe yii di kikojo, opo nnkan idagbasoke lo ti gbe se. Pataki ninu eyi ni iranlowo owo goboi ti won n fun awon akekoo to
wa ni ile-eko giga ni Naijiria. Egberun meedogbon naira ni won n fun akekoo kookan lodoodun. Akekoo bii metala ni n je anfaani
yii lodun kan. Titi ti akekoo bee yoo si fi pari eko re ni ile eko giga ni yoo ma je anfaani
naa niwon igba ti o ba ti n se daadaa ninu eko re. Odun bii merin sehin ni eto pataki yii ti bere.
Oloye Gbode ri gbo
pe egbe naa yoo maa se iranlowo fun awon omo egbe to ba jade ile iwe ni Amerika paapaa bere lati odun yii lo.
Lara
awon to se agbateru egbe yii ni Alagba Tolani Ogundiran ti o je Aare egbe naa ki o to di oloogbe ni odun 2004, Ojogbon Segun
Odesina, Alhaji Yekini Salami, Oloye R. Adedokun Atitebi, Diakoni Timothy Ayinla, Ogbeni Toye Okesola, Alhaja Yinka Atitebi,
Oloye Yinka Ayedun, Ogbeni Sunday Adegbola, Alhaja Adunola Salami, Ogbeni Adejare
ati Alagba Olaleye.
Lara awon
ti won fun dijo n gbe egbe yii ro ni Iyaafin Ayinla, Ogbeni Omodewu, Ogbeni Adesola Ige, Ogbeni Akande, Iyaafin Oladokun ati
Iyaafin Akande ati awon jankan jankan miran.
Olori Onigbeti waja
Olori Motunrayo Oyebisi ti i se iyawo keji Onigbeti ti ilu Igbeti, Oba Emmanuel
Oyekan Oyebisi Keji dagbere f’aye ni ojo’Ru ti i se ojo kerin osu kewaa odun 2006.
Ile iwosan kan ni ilu Ilorin,
Ipinle Kwara ni olori naa dake si. Ojo keji ni won gbe oku re wa si Igbeti nigba ti won si sin oku naa ni ojo’Bo ni
Igbeti.
Gbogbo eniyan lo n soro olori Motunrayo pelu edun okan nitori eni rere ni nigba
aye re.
Osise ijoba ibile Olorunsogo ni
eka eto ilera ni oloogbe naa je. Omo meji, Ponnle ati Mosunmola ni o fi s’aye lo.
Ilu Oyan ni o ti n sise tele. Lehin ti kabiyesi gun ori aga awon baba re ni
olori naa gba iwe isipopada (transfer) wa si Olorunsogo.
Ki Oluwa de’le
fun alaisi, ki ojo jinna sira, ase.